BBC News, Yorùbá - Ìròyìn
Ìròyìn tó ṣe kókó
Agbódegbà fáwọn Ajínigbé méjì la mú, ìrọ́ ni pé ọwọ́ tẹ afurasí agbébọn mẹ́rin ní pápákọ̀ òfurufú Akure - Ọlọ́pàá tako FAAN
Atẹjade kan ti agbẹnusọ fun ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh fisita lọjọ Aje lo fidi ọrọ yii mulẹ.
Ààyè ni màmá Deborah Adebola Fasoyin 'Ọdun ń lọ sópin' wà, kò kú – Mọ̀lẹ́bí
Kii ṣe igba akọkọ ree ti iroyin nipa iku mama yoo gbode ni Naijiria nigba ti ko si nnkan to ṣe mama.
Ìjà tí a kò mọwọ́ mẹsẹ̀ là ń jẹ́ lórí èlé owó epo, orí àgbà ẹ̀tù ní Nàíjíríà jókòó lé - NLC
Ọjọ Aiku ni ẹ́gbẹ osisẹ pe ipe yii ninu atẹjade kan to fi sita lati ke si ijọba pe ko pese eto iranwọ fọmọ Naijiria tori ele to gun owo epo.
Ọwọ́ àjọ NDLEA tẹ bàbá ẹni ọdún 74 pẹ̀lú oogun olóró l'Abuja
Papakọ ofurufu Nnamdi Azikiwe International Airport to wa niluu Abuja ni ọwọ ti ba baba naa pẹlu Cocaine ti wọn lo jẹ iwọn mọkanla (11 kilograms).
A fẹ́ ṣàfikún iná mọ̀nàmọ́ná tí à ń rà láti Naijiria, iná wọn ń ràn okòòwò àti lílò nílé wa lọ́wọ́ -Orílẹ̀èdè Togo
Adari ileeṣẹ NDPHC, Jennifer Adighije, lo sọ eyi di mimọ ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aiku oni, lẹyin ajọsọ ọrọ pẹlu ikọ onina mọnamọna to wa lati orilẹede Togo.
Ilẹ̀ rírì àti omiyalé gbẹ̀mí èèyàn 102 ní Ethiopia
Ṣaaju ni wọn ti kọkọ kede pe eeyan ọgbọn lo ku ki iye awọn to ku naa to tun le si laarin wakati mẹrinlelogun.
Ẹ wo bí aláboyún tó ń rọbí lọ́wọ́ ṣe gun ràkúnmí fún wákàtí méje láti dé iléèwòsàn
Awọn obinrin,mọlẹbi ati awọn ojulumọ lo n se iranwọ fun awọn alaboyun naa lati de ileewosan.
Wo ìbéèrè méje tí ọkùnrin kò gbọdọ̀ bi obìnrin
Ohun ti ọkunrin le mu mọra ko si ma binu si rara ni obinrin yoo sọ di babara, to si le binu rangbọndan.
Nítorí ìjàmbá ọkọ̀, ìjọba Ogun fẹ́ẹ́ fòfin de ọjà títà ní Sango Tollgate
Kọmiṣanna eto ayika nipinlẹ Ogun, Ola Oresanya, lo kede eyi lasiko abẹwo rẹ si agbegbe Sango Tollgate.
Gbálé-n-gbáta olóṣooṣù yóò bẹ̀rẹ̀ padà l'Eko lóṣù Kẹ́rin ọdún 2026 – Ìjọba Eko
Gẹgẹ bi Amofin Tokunbo Wahab; Kọmiṣanna fun eto ayika ati omi nipinlẹ Eko ṣe kede loni ọjọ Satide, o ni ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Kẹrin ọdun 2026 yii ni atunṣe ayika ti ọpọ eeyan maa n pe ni 'Ẹnfaromẹnta' naa yoo bẹrẹ pada kaakiri Eko.
Agbábọ́ọ̀lù Super Eagles nígbà kan rí, Henry Nwosu dágbére fáyé
Akẹgbẹ rẹ, Segun Odegbami, lo fi ikede iku agba ọjẹ agbabọọlu ọhun lede lọjọ Abamẹta.
Móríwú
BBC News Yorùbá ti wà lórí ìkànnì WhatsApp
Má jẹ́ kí etí rẹ ó di sí gbogbo ìròyìn ohun tó ń lọ ní Naijiria àti káàkiri àgbáyé. Mọ̀ nípa wọn lórí ìkànnì Whatsapp rẹ
Ìròyìn Àkàgbádùn
Ìgbà wo ni sísọ̀rọ̀ nípa ogun America- Israel àti Iran di ìwà ọ̀daràn ní Naijiria?
Iroyin sọ pe ninu ọsẹ yii, ẹka ọtẹlẹmuyẹ DSS nawọ gan awọn ọdọkunrin meji kan ni Kaduna, lori ohun ti wọn kọ soju opo ayelujara nipa ogun Iran ti America ati Israel bẹrẹ.
"Ẹ máà bínú bàbá,"- King Mitchy tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Ooni Ile Ifẹ
Ni ọsẹ melokan sẹyin ni iroyin gba ori ayelujara kan nigba ti King Mitchy kede pe oun ti tun awọn ile ẹkọ kan ṣe laarin ọsẹ mẹfa, to si n sọ pe ayipada to ye kooro le waye ni kiakia niwọn igba ti wọn ba ṣe e pẹlu ọkan ijolootọ.
Elena, Gbajúmọ̀ ayélujára kú lẹ́yìn tó ṣe iṣẹ́ abẹ láti fọn ìdí rẹ̀, ìjọba Eko bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Gẹ́gẹ́ bí àtẹ̀jáde tí àjọ náà ṣe sọ, wọ́n ní ohun tó ṣokùnfà ìdí táwọn fi ń ṣe ìwádìí náà ni ìròyìn tó gba orí ayélujára pé lẹ́yìn ìgbà díẹ̀ tí Elena ṣe iṣẹ́ abẹ náà ni ara rẹ̀ kò yá, kó tó di pé ó jáde láyé.
Aáwọ̀ bẹ́ sílẹ̀ láàárín APC àti Accord ní ìpínlẹ̀ Osun lórí ṣọ́ọ̀bù kíkọ́
Alaga ijọba ibilẹ Ariwa Ede, arakunrin Adeyemi Elliot to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC lo fẹ ṣe ifilọlẹ ṣọọbu igbalode si ọja Timi to wa ni agbegbe ki awọn janduku to ṣadede da eto naa ru.
Ohun tí a mọ̀ rèé lórí ìròyìn pé wọ́n yìnbọn fún Broda Shaggi ní Ogun
Gẹ́gẹ́ bí ìròyìn náà ṣe sọ, wọ́n sáré gbé Broda Shaggy lọ sílé ìwòsàn Blooming Care Hospital tó wà ní agbègbè Alakuko ní ìpínlẹ̀ Eko níbi tí wọ́n ti kọ́kọ́ tọ́jú rẹ̀.
Kókó ohun tí Mojtaba Khamenei sọ fún ìgbà àkọ́kọ́ lẹ́yìn tó di olórí Iran
Ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tí Mojtaba yóò sọ̀rọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ṣekúpa bàbá rẹ̀, Ayatollahi Ali Khamenei lọ́jọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù Kejì nígbà tí Amẹ́ríkà àti Israel pawọ́pọ̀ ṣe ìkọlù sí Iran.
LPDC da ẹ̀sùn ṣíṣe ayédèrú ìwẹ́ ẹ̀rí NYSC tí wọ́n fi kan igbákejì olórí ilé aṣojúṣòfin nù
LPDC tẹmpẹlẹmọ pé ohun tí wọ́n dá ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀ fún jẹ́ láti ṣe àmójútó àwọn amòfin tó wà lábẹ́ àjọ náà láti ri dájú pé wọ́n ń ṣiṣẹ́ wọn bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà lábẹ́ òfin kẹwàá ìwé òfin ìgbìmọ̀ náà.
Wá wí tẹnu rẹ o! Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ránṣẹ́ pe DPO àgọ́ ọlọ́pàá táráàlú ní afurasí ajínigbé tí sálọ
Yatọ si ọga ọlọpaa ti wọn fi si ahamọ naa, DPO ẹkun naa ati ASP gba iwe ẹsun lati ṣalaye ara wọn lori iṣẹlẹ ọhun pẹlu.
Àwọn olùwọ́de lu ìgboro Aba láti wọ́de pè fún ìtúsílẹ̀ Nnamdi Kanu
Gẹgẹ bi BBC Igbo ṣe fidi ẹ mulẹ, aago mẹsan-an aarọ ko ti I lu ti awọn oluwọde naa ti tu si oju opopo pẹlu awọn akọle ọlọkan-o-jọkan ti wọn fi n beere itusilẹ Nnamdi Kanu.
Ó ti yá jù fún kóòtù láti pàṣẹ pé mi ò lè dupò gómìnà mọ́- Aiyedatiwa
Ọjọbọ ana ti idajọ naa waye ni Aiyedatiwa ti fesi pada, nigba to n sọrọ lori eto ileeṣẹ amohunmaworan Channels kan.
Amẹrica kìlọ̀ fáwọn ọmọ orílẹ̀èdè rẹ̀ ní Naijiria, nítorí ìwọ́de Quds àwọn Shiites
Ayajọ Quds jẹ eyi ti awọn ijọ ẹlẹsin Islam IMN ti a tun mọ si Shiites gbe kalẹ.
Orin, Kò ṣe é má gbọ̀ ọ́, Duration 0,56
Kò ṣeé má gbọ̀ọ́
Kọ́milẹ́kọ̀ọ́
Ẹ tẹ̀lé wa lórí ìkànnì ayélujára
Ìwádìí kíkún lóríi kókó ìròyìn
Amẹrika ṣàlàyé ìgbà àti ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ tí ogun Iran yóò parí
Amẹrika sọ pe ogun naa n lọ bo ṣe yẹ ati wi pe o n yawọ ju bi awọn gan ṣe lero lọ.
Ẹ dákun ẹ gbà mí o, owó dísù ti fẹ́ gbẹ̀mí mi - Èèkàn òṣèré, Kunle Afolayan figbe ta
Oṣere tiata to tun jẹ adari awọn okoowo ati ibudo ti wọn ti n ya sinima ti wọn si tun n ṣe faaji, ṣalaye pe oun n na to miliọnu mọkanla (₦11 million ) lori disu rira laarin ọsẹ mẹrin si marun-un.
Ọkọ̀ bọ́ọ̀sì akèrò kó s'ódò nílùú Ibadan, èèyàn mẹ́ta kú
Eeyan mẹta lo padanu ẹmi ninu iṣẹlẹ yii, ti awọn marun un yooku si farapa yanayana.
Ọmọ Nàìjíríà kan, ọmọ Ghana méjì àtàwọn orílẹ̀ède 129 míì fara gbọgbẹ́ nínú ìkọlù àdó olóró Iran tó ti gbẹ̀mí èèyàn mẹ́fà ní UAE
Gẹgẹ bii awọn alaṣẹ Ghana ṣe sọ, ohun to jẹ ijọba Ghana logun ju ni abo ẹmi ati dukia awọn eeyan rẹ nibikibi ti wọn ba wa lagbaye.
Ọwọ́ tẹ àwọn afurasí ọ̀daràn 99 ní ìpínlẹ̀ Ondo
Atẹjade kan ti agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abayomi Jimoh fi lede ni ilu Akure ti n ṣe olu ilu ipinlẹ Ondo sọ pe Ọjọ Kẹjọ, oṣu Kẹta ọdun 2026 ni awọn ẹṣọ aabo ṣe iṣẹ naa lati daabo bo dukia ati ẹmi awọn ara ilu.
Ohun tí a mọ̀ rèé nípa ìjà ńlá tó bẹ́ sílẹ̀ láàárín àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Oyo
BBC News Yoruba kan si igun mejeeji to wa lẹgbẹ oṣelu PDP ipinlẹ Oyo lati fidi ohun to ṣẹlẹ Abamẹta mulẹ
Ilé ẹjọ́ Kòtẹ́milọ́rùn gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí àpérò ẹgbẹ́ òṣèlú PDP tó wáyé ní Ibadan
Ilé ẹjọ́ náà ní ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tí PDP pè kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ àti pé ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gíga kọ́kọ́ gbé kalẹ̀ lọ́jọ́ Kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Kẹwàá jẹ́ ohun tó tọ̀nà.
Wọ́n bá òkú ọmọbìnrin kan lẹ́nu ọ̀nà ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀, Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá bẹ̀rẹ̀ ìwádìí
Agbẹnusọ ọlapàá Oyo, Ayanlade Olayinka nínú àtẹ̀jáde kan tó fi léde sọ pé Quadri Mohammed ni orúkọ ọ̀rẹ́kùnrin tí wọ́n fura pé ó ṣekúpa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Precious.
A gbọ́dọ̀ gba ilẹ̀ wa padà lọ́wọ́ àwọn agbèṣùmọ̀mí - ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá Tunji Disu fọnmú
Disu sọ eyi ninu ọrọ rẹ nigba to ṣe abẹwo si ilu Ilorin, olu ilu ipinlẹ Kwara lori ipo ti ipinlẹ naa wa lori eto aabo.
Wo àwọn ọmọ Nàìjíríà mẹ́rin tó wà nínú àwọn bilọníà nílẹ̀ Africa
Nínú àbọ̀ ìwádìí Forbes magazine fún ti ọdún 2026 sọ pé àwọn olówò tí owó wọn ti wọ bilọníà ní ilẹ̀ Africa ti lékún pẹ̀lú ìdá mẹ́tàlélógún tí a bá ṣe àgbéyẹ̀wò rẹ̀ sí ti ọdún 2025.













































































